Marilyn Gillies Carr

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Marilyn Gillies Carr (tí a bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejìlá ọdún 1941) jẹ́ obìnrin ará ilẹ̀ Scotland, tó wá láti Dundee. Ìgbà tí wọ́n bí, kò ní apá bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ọwọ́, ẹsẹ̀ rè ló fi máa ń mú gbogbo nǹkan tó bá fẹ́ mú. [1]

Ó farahàn nínú fíìmù Two of a Kind pẹ̀lú Douglas Bader ní ọdún 1971. Fíìmù yìí dá lórí ayé arákùnrin yìí tí wọ́n ti gé ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì, àti arábìnrin yìí tió wọ́n bí láisì apá àti ọwọ́. Ètò náà fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan hàn nípa ìgbésí ayé Marilyn, bí ó ṣe ń ṣe iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀, ní ilé, ibiṣẹ́, àti bí ó ṣe ń wa ọkọ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó tún farahàn nínú ètò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòán kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "The Wednesday People", ní ọdún 1972.

Orúkọ ọkọ́ tí ó fẹ́ ní Barry Carr, tó jẹ́ awakọ̀ ojú-òfuurufú, tí wọ́n sì fẹ́ ara wọn ní ọdún 1973. Marilyn ti jẹ́ alátìlẹ̀yìn Douglas Bader Community Garden Charity, tó wà ní Cupar, ní Fife. Marilyn jẹ́ alága ẹgbẹ́ náà fún ìgbà díẹ̀, kí ó tó fi ipò náà sílẹ̀ fún ìdí tó yé òun tìkararẹ̀.

Ó kópa nínú ètò ìṣèlú ti Croydon North West ní ọdún 1981, gẹ́gẹ́ bí i olùdíje dúpò Olómìnira Pro-Life. Ó gba ìbò 340, èyí tó jẹ́ ìdá kan (1%) gbogbo ìbò náà lápaapọ̀. Malcolm Muggeridge jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní àkọ́kọ́ yìí.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Carr, Marilyn (1982). Look No Hands!. Edinburgh: Canongate. ISBN 0-86241-037-1.