Roseline Adewuyi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Roseline Adewuyi
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́Bachelor of Arts (BA), Obafemi Awolowo University; MA, University of Ibadan
Iṣẹ́Social educator, Gender advocate and Blogger
Ìgbà iṣẹ́2014–present

Roseline Adebimpe Adewuyi jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ àwùjọ àti aṣègbè fábo.[1][2] Ní ọdún 2020, ó wà lára àwọn ọgọ́ta obìnrin tí BusinessDay Women's Hub ṣàfihàn rẹ̀ ní ayẹyẹ ìgbòmìnira ti ọgọ́ta ọdún.[3] Bákan náà ni ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Dalai Lama Fellowship,[4] èyí tí ó darapọ̀ mọ́ ní ọdún 2018, nítorí iṣé ribiribi rẹ̀ lórí ìdàgbàsókè àwọn ọmọdébìnrin.[5][6]

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adewuyi jẹ́ ọmọ ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínú ẹ̀kọ́ èdè Faransé láti Obafemi Awolowo University, àti oyè M.A láti University of Ibadan.[7][8]

Iṣẹ́ rẹ̀ àti jíjà fétọ̀ọ́-ọmọnìyàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iṣẹ́ tí Adewuyi yàn láàyò ni láti kọ́ àwọn ọmọdébìnrin láti wà ní pípé, tí wọ́n lè gbẹ́kèlé ara wọn, àti láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo àìṣedédé tó ní ṣe pẹ̀lú abo.[9]

Ní ọdún 2018, Adewuyi bẹ̀rè sí ní kọ àyọkà sí orí ìtàkùn ayélujára rẹ̀ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn àyọkà yìí sì dá lórí àwọn ọmọdébìnrin ilẹ̀ Africa, bẹ́ẹ̀ sì ni ó ń ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ wọn ní àwọn iṣẹ́ tó máa wúlò fún wọn ní ọjọ́ iwájú láti jẹ́ aṣíwájú rere.[10][11][12]

Àsìkò tí ó fi ń ṣe National Youth Service corps ló lò fún iṣẹ́ yìí, tó sì mu gba àmì-ẹ̀yẹ, gẹ́gẹ́ bí i agùnbánirọ̀ tó dára jù ní Ìpínlẹ̀ Kwara, látàti àwọn iṣẹ́ ribiribi rè fún ìdàgbàsókè àwùjọ.[13]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Gender advocate, Roseline Adewuyi, celebrates three years of blogging". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-09-01. Retrieved 2021-09-30. 
  2. NewsDirect (2022-04-15). "Education, key to gender-inclusive society — Roseline Adewuyi". Nigeriannewsdirectcom (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-02-09. Retrieved 2022-07-19. 
  3. "I teach young girls to discard society's scripts and follow their individual purpose —Roseline Adewuyi, social educator and gender advocate". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-10-10. Retrieved 2021-09-30. 
  4. "DALAI LAMA FELLOWS". DALAI LAMA FELLOWS (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-15. 
  5. "Adewuyi: Being gender advocate is not for the faint hearted". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-05. Retrieved 2021-09-30. 
  6. "Spotlight on France - France encourages new generation of global citizens through Labcitoyen programme". RFI (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-07-11. Retrieved 2021-09-30. 
  7. "#Interview | "My Advocacy Is Focused On Breaking Sterotypes" - Roseline Adewuyi". Women of Rubies (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-01. Retrieved 2021-09-30. 
  8. "Here Are All The Amazing Things Roseline Adewuyi Is Doing To Advocate For The Girl Child". Woman.NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-10-14. Retrieved 2021-11-15. 
  9. Crown, Adejola Adeyemi (2021-10-16). "Abandon Societal Constructs Inimical To Your Personal Growth - Gender Advocate, Roseline Adebimpe Adewuyi Enjoins Girl-Child". Tropic Reporters (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-11-15. Retrieved 2021-11-15. 
  10. "Roseline Adebimpe Adewuyi - Global Youth Ambassador April 2022". Theirworld (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-19. 
  11. "INTERVIEW: Nigerian women must join forces to break biases limiting them, says Roseline Adewuyi". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-03-08. Retrieved 2022-07-19. 
  12. News (2021-09-01). "Gender advocate, Roseline Adewuyi, celebrates three years of blogging". Orombo (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-15. 
  13. "NYSC served as bedrock of my civic engagement journey ― Gender Advocate, Roseline Adewuyi". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-07. Retrieved 2022-05-05.