Lucy Allais

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Lucy Allais jẹ onímọ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìmòye, tó jẹ́ olùkọ́ ní University of Witwatersrand àti John Hopkins University.[1] Àwọn iṣẹ́-ìwádìí rẹ̀ dá lórí ìwòye Immanuel Kant lórí ìdáríjì, ìjìyà àti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀. [2]

Ètò ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Allais gba oyè ẹ̀kọ́ nínú ẹ̀kọ́ ìmòyè ní University of Witwatersrand (Wits), ní Johannesburg, lẹ́yìn náà ló gba oyè ẹ̀kọ́ (B.Phil.) àti D.Phil. ní University of Oxford. Ó sì tẹ̀síwájú láti lọ máa ṣiṣẹ́ olùkọ́ni ní Oxfors fún ọdún mẹ́ta léyìn tó gba oyè D.Phil., kí ó ṣẹ̀ tó wá lọ sí University of Sussex ní ọdún 2004. Láàárín ọdún 2006 àti 2008 Dr. Allais ṣiṣẹ́ olùkọ́ni ní University of Witwatersrand. Ní ọdún 2008, Allais bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ̀na méjì ní University of the Witwatersrand, níbi tí ó ti jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, àti University of Sussex.[3] Ní ọdún 2014 ó kúrò ní Sussex lọ sí University of California, San Diego, gẹ́gẹ́ bí i Henry E. Allison, tó sì jẹ́ alága History of Philosophy, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ náà pọ̀ mọ́ Witwatersrand.[4] [5] Ó fi UCSD sílẹ̀ láti lọ sí Johns Hopkins ń ọdún 2021.[6]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Welcome New Faculty". 
  2. UC San Diego Philosophy Faculty .
  3. Dr Lucy Allais .
  4. Featured Philosop-her: Lucy Allais .
  5. Lucy Allais (Sussex, Witwatersrand) half-time to UC San Diego .
  6. "Welcome New Faculty".